2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.
3 Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹlórí ilẹ̀ àwọn olódodo,kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.
4 OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,ati fún àwọn olódodo.
5 Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹàwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.Alaafia fún Israẹli!