1 Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.
2 Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.
3 Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.
4 Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni.