1 Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,
2 “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,sibẹ, wọn kò borí mi.”
3 Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.
4 Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.