1 OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga,bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè.N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá,n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ.
2 Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́,bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀.Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́.
3 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.