1 Ẹ wá, ẹ yin OLUWA,gbogbo ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ń sìn ín ninu ilé rẹ̀ lóru.
2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè, kí ẹ gbadura ninu ilé mímọ́ rẹ̀,kí ẹ sì yin OLUWA.
3 Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayébukun yín láti Sioni wá.