1 Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún,nígbà tí a ranti Sioni.
2 Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí,
3 nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùnti ní kí á kọrin fún àwọn.Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”
4 Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?
5 Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.