5 Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.
6 Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,bí n kò bá ranti rẹ,bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.
7 OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣenígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí wọn ń pariwo pé,“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”
8 Babiloni! Ìwọ apanirun!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!
9 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ,tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta.