13 Nítorí ìwọ ni o dá inú mi,ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.
14 Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́;ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!O mọ̀ mí dájú.
15 Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀,tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí,kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ.
16 Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi,o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún misinu ìwé rẹ,kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
17 Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi!Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye.
18 Bí mo bá ní kí n kà wọ́n,wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ;nígbà tí mo bá sì jí,ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà.
19 Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú,kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.