21 OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ;mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?
22 Mo kórìíra wọn dé òpin;ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún.
23 Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi;yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi.
24 Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀,kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé.