1 Mo ké pe OLUWA,mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i.
2 Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀,mo sọ ìṣòro mi fún un.
3 Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì,ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà.Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún miní ọ̀nà tí mò ń rìn.
4 Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká,mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi;kò sí ààbò fún mi,ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.
5 Mo ké pè ọ́, OLUWA,mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.”
6 Gbọ́ igbe mi;nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata.Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi,nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
7 Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́,kí n lè yin orúkọ rẹ lógo.Àwọn olódodo yóo yí mi ká,nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi.