3 OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ;àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀.
4 Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ,tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ.
5 Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ,ati iṣẹ́ ìyanu rẹ.
6 Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu,èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ.
7 Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó,wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ.
8 Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni;kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.
9 OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan,àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá.