1 Ẹ yin OLUWA!Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,ẹ yìn ín lókè ọ̀run.
2 Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀;ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.
3 Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá;ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn.
4 Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.
5 Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.