11 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;
12 ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà.
13 Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.
14 Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára,ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn;ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.Ẹ yin OLUWA!