5 Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.
6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá.
7 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;
8 iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.
9 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;
10 ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò.
11 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;