7 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;
8 iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.
9 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;
10 ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò.
11 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;
12 ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà.
13 Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.