1 Ẹ yin OLUWA!Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́.
2 Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀,kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba.
3 Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀,kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i.
4 Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.