4 Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.
5 Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá;kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.
6 Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun;kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn,
7 láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà;
8 láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn,ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn;
9 láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀.Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí.Ẹ yin OLUWA!