3 Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn;
4 sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já,ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé.Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,
5 tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀,ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje.
6 Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.
7 Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
8 Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.
9 Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.