1 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfùtí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?
2 Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.
3 Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá jákí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”
4 Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.
5 Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,
6 Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”
7 N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ.