1 OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú,orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́.
2 Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá,yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3 Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ.
4 Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ.
5 Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.