3 Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ.
4 Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ.
5 Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.
6 Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́;OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wáyóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá.
7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa.
8 Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.
9 Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.