1 Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA;inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́!
2 O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́,o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú.
3 O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀;o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí.
4 Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.