2 O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́,o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú.
3 O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀;o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí.
4 Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.
5 Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́;o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀.
6 Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae;o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀.
7 Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA;a kò ní ṣí i ní ipò pada,nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀.
8 Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ.