12 Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù,wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun,bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù.
14 Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé;ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.
15 Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.
16 Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;àwọn aṣebi dòòyì ká mi;wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.
17 Mo lè ka gbogbo egungun miwọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.