13 Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun,bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù.
14 Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé;ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.
15 Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.
16 Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;àwọn aṣebi dòòyì ká mi;wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.
17 Mo lè ka gbogbo egungun miwọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.
19 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi!Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́!