1 OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi,n kò ní ṣe àìní ohunkohun.
2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù,ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́;
3 ó sọ agbára mi dọ̀tun.Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodonítorí orúkọ rẹ̀.
4 Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú,n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;nítorí tí o wà pẹlu mi;ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.