1 OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi,n kò ní ṣe àìní ohunkohun.
2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù,ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́;
3 ó sọ agbára mi dọ̀tun.Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodonítorí orúkọ rẹ̀.
4 Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú,n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;nítorí tí o wà pẹlu mi;ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.
5 O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi,níṣojú àwọn ọ̀tá mi;o da òróró sí mi lórí;o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri,ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae.