1 OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wàninu rẹ̀,òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tíń gbé inú rẹ̀;
2 nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi.
3 Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀?
4 Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,tí kò sì búra èké.
5 Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀.
6 Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA,àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu.
7 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé.