7 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé.
8 Ta ni Ọba ògo yìí?OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára,OLUWA tí ó lágbára lógun.
9 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,kí Ọba ògo lè wọlé.
10 Ta ni Ọba ògo yìí?OLUWA àwọn ọmọ ogun,òun ni Ọba ògo náà.