1 Dá mi láre, OLUWA,nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn,mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì.
2 Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò;yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́,mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn.
4 N kò jókòó ti àwọn èké,n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn;
5 mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi,n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀.
6 Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.