3 OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkúo sọ mí di ààyè láàrin àwọn tíwọ́n ti wọ inú kòtò.
4 Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.
5 Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀,ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀;eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́,ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀.
6 Nígbà tí ara rọ̀ mí,mo wí ninu ọkàn mi pé,kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae.
7 Nípa ojurere rẹ, OLUWA,o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá;ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi,ìdààmú dé bá mi.
8 Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA,OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀.
9 Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú?Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò?Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ?