1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní:OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú.
2 OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
3 Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,OLUWA yóo fún un lókun;ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.
4 Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;mo ti ṣẹ̀ ọ́.”
5 Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”