2 OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
3 Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,OLUWA yóo fún un lókun;ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.
4 Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;mo ti ṣẹ̀ ọ́.”
5 Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”
6 Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìíni yóo máa sọ;bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.Nígbà tí ó bá jáde,yóo máa rò mí kiri.
7 Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mijọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi;ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi.
8 Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀;kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.”