9 Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé,tí ó ń jẹun nílé mi,ó ti kẹ̀yìn sí mí.
10 Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi;gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un.
11 Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi,nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi.
12 O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi,o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae.