1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun.
2 Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa.
4 Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn.