6 Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn;Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn!
8 Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọpẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu.Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé;òun ni ọlọ́lá jùlọ!