1 Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé,“Kò sí Ọlọrun.”Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe,kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.
2 Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá,ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé,àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun.
3 Gbogbo wọn ni ó ti yapa;tí wọn sì ti bàjẹ́,kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo.
4 Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun.