4 Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.
5 Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi;OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run.
6 N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ,n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA,nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.
7 O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi,mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.