5 Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.
6 Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.
7 Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀.
8 O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ.
9 A óo lé àwọn ọ̀tá mi padaní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.
10 Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;
11 Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?