3 Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!
4 Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,ahọ́n wọn sì dàbí idà.
5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.
6 Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;ìpọ́njú dorí mi kodò.Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i.
7 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,ọkàn mi dúró ṣinṣin!N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.
8 Jí, ìwọ ọkàn mi!Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu.
9 OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.