8 Jí, ìwọ ọkàn mi!Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu.
9 OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.
11 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.