3 Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,tí wọn ń purọ́.
4 Wọ́n ní oró bí oró ejò,wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,
5 kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,tabi ìpè adáhunṣe.
6 Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun.
7 Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.
8 Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí.
9 Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ.