13 fi ibinu pa wọ́n run.Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́,kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu,ati títí dé òpin ayé.
14 Ní alaalẹ́ wọn á pada wáwọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú.
15 Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri,bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn.
16 Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ;n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tíkì í yẹ̀.Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi miìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú.
17 Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi,Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí.