8 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín,o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́.
9 Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi.
10 Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀;Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi.
11 Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé;fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n,ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa!
12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá,àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ,jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn.Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa,
13 fi ibinu pa wọ́n run.Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́,kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu,ati títí dé òpin ayé.
14 Ní alaalẹ́ wọn á pada wáwọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú.