1 OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.
2 Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.
3 Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?
4 OLUWA, pada wá gbà mí,gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
5 Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?
6 Ìkérora dá mi lágara:ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.