6 Ìkérora dá mi lágara:ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.
7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá.
8 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi.
9 OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi.
10 Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi;ìdààmú ńlá yóo bá wọn,wọn óo sá pada,ojú yóo sì tì wọ́n lójijì.