1 Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,o ti wó odi wa;o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò.
2 O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;o ti mú kí ó yanu;dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì.
3 O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.
4 O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá.