4 O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá.
5 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa,kí o sì dá wa lóhùn.
6 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,n óo sì pín àfonífojì Sukotu.
7 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
8 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi;lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé;n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.”
9 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?
10 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.