1 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé;ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.
2 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.
3 Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa,ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya?
4 Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀.Inú wọn a máa dùn sí irọ́.Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́.
5 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé,nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.
6 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.