3 Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa,ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya?
4 Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀.Inú wọn a máa dùn sí irọ́.Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́.
5 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé,nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.
6 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.
7 Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà;òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi.
8 Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan;ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀;OLUWA ni ààbò wa.
9 Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù;ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá;bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n;àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ.